Ibadan Ilu Ori oke
Ilu Ibukun Oluwa
K’Oluwa se o nibukun
Fun Onile at’Alejo

Egbe: Eho e yo ke si gberin
Ogo f’Olorun wa Io’orun
Ibukun ti Obangiji
Wa pelu re wo Ibadan

Ibadan ilu to ngbajeji
Tiko si gbagbe omo re
Kife ara ko wa sibe
Fun Onile at’Alejo

Egbe: Eho e yo ke si gberin

Ibadan, ilu Jagunjagun
Awon to so o dilu nla
Awa omo re ko ni je
K’ola ti ogo won run

Egbe: Eho e yo ke si gberin

Mo wo lati ori oke
Bi ewa re ti dara to
B’odo re ko tile dara
Sibe o Ia Ibadan ja

Egbe: Eho e yo ke si gberin

Ibadan ilu ori oke
K’Oluwa se o nibukun
Ki gbogbo Joye inu re
Je elemi gigun fun wa

Egbe: Eho eho ke si gberin